Ifoya ko si fawọn to wa ni Oke-Okun lakooko yii lati fi owo wọn gbe nnkan rere ṣe lori ile gbigbe – Oludasile Pelican Valley
Dokita Babatunde Adeyẹmọ, gbajumọ ninu awọn to n ta ilẹ, to ṣee gbọkanle,laini idunkoko kankan, to nileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ, ti rọ gbogbo awọn to wa ni Oke-okun lati fọkan wọn fun idokoowo lori ohun to jẹ mọ ilẹ ati dukia lakooko yii, nitori pe igba yii lo dara ju laini ifoya kankan.